Eyi Ni Aṣiri Bi Ijọba Ti Doola Awọn Akẹẹkọ ati Olukọ Ti Won Jigbe Nipinlẹ Ọyọ
Leyin ti ariwo ayọ ta gee laarin ilu l’atari pe gbogbo awọn akẹẹkọ ati olukọ ti awọn ajinigbe-agbesunmọmi palẹ wọn mọ ni ijọba ibilẹ Oriire ni ipinlẹ Ọyọ ni ọjọ kẹẹdogun oṣu karun-un ọdun 2026 ni awọn eleto aabo doola l’ayọ ati alaafia.
L’ọwọ yii, aṣiri bii idoola alagbara naa ti waye ti bẹrẹ si ni ja’de si’ta. Ile-iṣẹ eleto aabo ilẹ yii ti fi ọrọ si’ta, bẹẹ ni Gomina Ṣeyi Makinde ipinlẹ Ọyọ naa ti ba awọn oniroyin s’ọrọ l’ori aṣeyọri yii.
Bẹẹ o ba gbagbe, gbajugbaja iransẹ Ọlọrun, Baba E.A Adeboye ti inu ijọ Redeem ti sọ bi ọjọ melo kan ṣaaju ki wọn to ri awọn ọmọ naa at’awọn olukọ wọn doola pe ọna ara ati iyanu ni kinni yoo jẹ.
Iroyin to n le’de bayii gẹgẹ bii ile-iṣẹ eleto aabo ṣe fi si’ta ni pe aparapọ gbogbo ikọ eleto aabo lo bi aṣeyọri naa, lat’ori awọn ologun, to fi d’ori awọn ọlọpa, awọn otẹlẹmuyẹ, awọn ọdẹ ibilẹ, awọn Amọtẹkun, to fi mọ awọn ikọ afarjọlogun ati awọn ikọ ojulalakan-fi-n-ṣọri miiran.
Wọn jẹ ko di mimọ pe akitiyan akọṣẹmọṣẹ ni’di ọrọ eto aabo, imọ ẹrọ igbalode to lekenka ati ifimufinlẹ alagbara lo bi aṣeyọri naa to wa’ye nitori ohun to le pupọ ni oṣu kan ni wọn fi n to ipasẹ awọn ajinigbe-agbesunmọmi naa lati lee doola awọn eeyan naa layọ.
Ko tan si’bẹ, arakunrin kan to jẹ oṣiṣẹ ajọ otẹlẹmuyẹ DSS tẹlẹ, Ọmọwe Ṣeyi Adetayọ tun sọ di mimọ l’ori amohunmaworan pe iṣẹ nla ni lati ri awọn eniyan naa doola looyẹ, l’eyi to si gba awọn eleto aabo ni ọpọlọpọ ọjọ ki isẹgun to de.
Ninu ọrọ rẹ, o tọka si pe ijinigbe to waye ni ipinlẹ Ọyọ naa ko deede wa’ye koda awọn ajinigbe-agbesunmọmi to wa ni’di ikọlu naa mọọmọ ṣe ikọlu naa ni, nitori a ti gba awọn meji kan to jẹ ọga wọn ṣugbọn ti ijọba ti mu da si ewọn silẹ.
O tun tọka si pe, awọn agbesunmọmi ti kọkọ ṣe ikilọ si awọn ọgba itunirọ kọọkan ni ipinlẹ Niger ati ibomiran nitori ati gba awọn ọga wọn silẹ ṣugbọn to ja si pabo. Eyi gan-an lo fa ti wọn fi pada wa lẹyin asiko diẹ lati wa ṣe ikọlu to waye nipinlẹ Ọyọ boya yoo le ka Aarẹ Bọla Tinubu l’ara lati le da awọn ọga wọn silẹ.
Adetayọ tun tẹsiwaju pe, ohun ti awọn eleto aabo kọkọ ṣe ni lati dooyi ka awọn agbesunmọmi naa ninu igbo ti wọn f’ara pamọ si, lẹyin naa wọn bẹrẹ si ni mu awọn mọlebi ati alabaṣe awọn agbesunmọmi naa to wa laarin igboro, bẹẹ ni wọn bẹrẹ si ni ba awọn ibuba wọn jẹ ko to di pe ọwọ wa pada tẹ wọn, botilẹjẹ pe ile-iṣẹ eleto aabo ni awọn eleto aabo kọọkan fi ẹmi wọn di iṣẹ idoola naa lati ṣe aṣeyọri.
Ẹwẹ, ninu ọrọ Gomina Ṣeyi Makinde ipinlẹ Ọyọ, ẹni t’oun naa ti ṣe abẹwo si awọn eniyan naa ni ile-iwosan to pamọ ti wọn ti n gba itọju l’ọwọ. Gomina ni awọn dupẹ pe awọn eeyan naa ti pada wọ ilu wa, ti ọrọ yii abi asiko yii gan-an kii ṣe ohun ti ẹnikẹni fi gbọdọ ṣe oṣelu. Gomina bii ọpọlọpọ awọn ara ilu lo ṣe sadankata fun awọn eleto aabo.