Eyi Kamama! Ẹ Wa Gbọ Iye Ti Davido L’oun Ma N Na L’oṣoṣu

Eyi Kamama! Ẹ Wa Gbọ Iye Ti Davido L'oun Ma N Na L'oṣoṣu

Gbajugbaja onkọrin ilẹ wa David Adeleke ti gbogbo aye mọ si Davido lo ma ti s’ọrọ to da ariwo si’lẹ l’ori ayelujara ati l’aarin igboro wayii.

Davido lo sọ l’asiko to wa l’ori ila l’ori ayelujara pẹlu ọmọkunrin kan ti wọn pe ni Davrel, ni bẹ lo ti pe, l’aarin oṣu kan, ẹgbẹlẹgbẹ owo ni oun maa n naa, l’aarin ọọdunrun si irinwo miliọnu naira iyẹn #300m si #400m l’oṣoṣu.

 

Eeyan o ṣe bi gbogbo rẹ ti tan si’bẹ ni, Davido ti wọn a tun ma pe ni – Ọmọ Baba Olowo, abi O.B.O ba tun ṣ’aleye pe, owo t’oun sọ yii ko mọ owo t’oun ma a fun aya rẹ, Chioma ati awọn to ku ni’le, bẹẹ ọtọ tun l’owo t’oun fi n ra awọn ọkọ to le ku, awọn ọkọ erẹntẹ, ati awọn ohun ọṣọ ara to jẹ olowo iyebiye.

Ki ni Ọmọ Baba Olowo s’ọrọ yii si, l’oriṣiriṣi awọn eniyan ba bẹrẹ si ni m’ẹnu le ọrọ naa kankankan, awọn kan n pe bẹẹni ni ti Davido ri, Olowo Ọmọ Baba Olowo. Awọn mioran ni, n jẹ owo yii o wa pọ l’apọju bayii? Ni’bẹ naa la tun ti ri awọn ti wọn pe l’aye l’aye, awọn o ni ba iṣẹ mu’lẹ l’aye awọn! Bẹẹ la ri awọn miiran ti wọn pe, iye ti O.B.O iba ri abi naa l’oṣoṣu ko gba ibikankan kan awọn rara, bo ba ṣe wu alaye ni ko ṣe lo o.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search