O Ma Ṣe O, Iku Doro!Ẹgbọn Ọọni Ile-Ifẹ Jade Laye

O Ma Ṣe O, Iku Doro!Ẹgbọn Ọọni Ile-Ifẹ Jade Laye

Ẹgbọn Ori ade, Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Ẹnitan Adeyeye Ogunwusi  (Ojaja keji), Ọmọ-ọba Adetunji Ogunwusi ti gb’ẹmi mi.

Ninu atẹjade kan ti oludari iroyin ati ipolongo ni aafin Ọọni, Sodiq Lawal buwọlu, Ọọni ṣapejuwe ẹgbọn rẹ gẹgẹ bi oniṣowo to dantọ ti igbe-aye rẹ ṣafihan iwa irẹlẹ ati ṣiṣe daadaa si awọn eeyan.

Atẹjade naa ni iku Ọmọ-ọba naa ti fi aaye ti ko ṣe di silẹ ninu ẹbi Ogunwusi, ile ọba Ojaja ati gbogbo ilu Ile-Ifẹ pata.

Gẹgẹ bi Ori Ade naa ṣe sọ, o ṣapejuwe ẹgbọn rẹ gẹgẹ bi ẹni to ṣe aṣeyọri ninu iṣowo ṣugbọn o ṣi n ṣe daadaa si awọn eeyan.

Ọmọ-ọba Adetunji ni wọn bi ni ọjọ kẹjọ, oṣu kejila ọdun 1967 to si jẹ ẹgbọn fun Ọọni Ile-Ifẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search