Wahala Nla Bẹ Silẹ L'aarin Ọbasanjọ, Tinubu, Atiku ati Ọṣọba?
Ṣe wọn ni iyan ogun odun a ma gbona fẹlifẹli to si le jo’ni l’ọwọ, agbo oṣelu lo ti n ho gudugudu yatọ lati bi ọjọ meji, ti awọn agbagba oloṣelu si n ko ilali funra wọn ni gbangba lai bikita.
Koda Ẹbọra Owu iyẹn aarẹ tẹlẹ ri ni Naijiria, Oluṣẹgun Ọbasanjọ gan-an ti pada si’di kikọ lẹta gbọngbọnran t’aye mọ mọ tẹlẹ bo ba ti l’ọrọ to fẹ sọ k’aye gbọ.
Ki lo fa idi ọrọ gan-an? Ti eti Bọla Tinubu aarẹ Naijiria l’ọwọ yii, ati Atiku Abubakar to ti fi’gba kan ri jẹ igbakeji aarẹ l’aye ijọba Ọbasanjọ ṣe n gbọ ọrọ buruku ti ikun n gbọ ti eti rẹ fi di.
Ṣebi ọkan ninu awọn agbagba to jẹ iṣẹ’bi ni’lẹ Yoruba to tun jẹ gomina tẹlẹ ri ni’pinlẹ Ogun, Arẹmọ Olusẹgun Ọṣọba ni ọrọ apilẹkọ rẹ kan ja’de ninu atẹjade kan lat’ọwọ ile-iṣẹ The Legal Observer ni ogun’jọ oṣu keje ọdun 2026 ta wa yii.
Koko ọrọ Ọṣọba ninu atẹjade naa ni pe eru ni Ọbasanjọ fi gba ibukun l’ọwọ awọn t’awọn jẹ gomina l’awọn ipinlẹ mẹfa ilẹ Yoruba ninu eto idibo ọdun 2003. Ọṣọba niẹtan oṣelu ati iwa aiṣododo haran-un ni Ọbasanjọ fi fi burẹdi ko wọn ni omi ọbẹ lọ ninu ẹgbẹ AD ni’gba naa ati ẹgbẹ Afẹnifẹre.
Panran ti Ọbasanjọ yoo f’esi, lo ba ki lẹta mọlẹ, Baba Iyabọ kọ’we naa, o gun gban-na-gban-na, kekere kọ rara. Ọbasanjọ o b’eṣu bẹ’gba, lo ba fi lẹta ta si Arẹmọ Ọṣọba pada.
Afi bi Ṣango Olukoso, a-ja-ma-m’ala, ọ-b’ẹnikan-ja f’ọwọ-rọ-gbogbo-ile-ni’mu. Ni Ọbasanjọ ba tun ta si Tinubu, to si tun ju ogulutu lu Atiku.
Ninu ọrọ Ọbasanjọ lailai ki Ọṣọba dẹkun ati ma sọ bẹẹ kiri pe oun fi ẹtan b’awọn lo jẹ ki wọn padanu ibo ọdun 2003. Iyẹn ibo ọdun bii mejila s’ẹyin.
Ọbasanjọ ni ọpọlọpọ nnkan ni ko ye Ọṣọba nitori ọjọ-ori oṣelu rẹ nigba naa ko gbe, ati pe awọn gomina to padanu ibo l’ọdun 2003 l’ẹkun iwọorun guusu nigba naa ni ko gbaradi to, t’oun si tun ri mọ pe wọn ko fa’lẹ mọ iponlogo ibo wọn l’asiko naa l’eyi to pada mu ki awọn marun-un ninu gomina mẹfa ti ẹgbẹ AD ni nigba yẹn padanu s’ọwọ ẹgbẹ oṣelu PDP l’ọdun 2003.
Yatọ fun eyi, Ọbasanjọ tun tọka si pe ọpọlọpọ adehun t’awọn oloṣelu inu ẹgbẹ AD ati awọn aṣaaju ẹgbẹ Afẹnifẹre l’ero pe awọn jọ ni, Atiku ni wọn n ba du’na-du’ra l’orukọ oun, l’eyi to si jẹ pe Atiku gan-an n d’ọwọ wu nitori lati ọjọ ti wọn ti bura wọ’le f’oun Ọbasanjọ ati igbakeji rẹ Atiku ni Atiku ti bẹrẹ si ni sa’re ṣe kirakita lati di aarẹ. Ọbasanjọ ni imọsi oun kọ ni ohunkohun ti wọn ba ni l’adehun.
L’ori ẹsun eyi, Atiku pẹlu ẹni to jẹ pe titi di asiko yii ṣi n tiraka lati di aarẹ orilẹ-ede Naijiria ni ko ro pe ẹẹmeji lati da ọga rẹ atijọ l’ohun, o ni ara lo ṣi n ta Ọbasanjọ nitori awọn di’na mọ nigba to fẹ ṣe saa kẹta ti ofin o f’aye gba, o ni eyi gan-an l’oun dun Baba Iyabọ, to si jẹ oun to dun ni jọjọ pe iru baba agbalagba naa ṣi n ran’ro.
Ko tan si’bẹ Atiku ba tun ni, ki Ọbasanjọ ma wu’lẹ pẹ kọrọ lati tako ipolongo oun lati di aarẹ nitori Tinubu ti wọn jọ jẹ elede kan-naa. O pa aṣamọ aito eyin ka la n d’ọwọ bo fun Ọbasanjọ.
Pada sinu lẹta Ọbasanjọ yii kan-naa, Baba Iyabọ ni ninu gomina mẹfa lati inu ẹgbẹ oṣelu AD, marun-un padanu ipo wọn nitori bẹẹ ni ibo wi. O ni koda ẹyọkan to ku iyẹn ipinlẹ Eko labẹ iṣakoso Bọla Tinubu gẹgẹ bii gomina, oun ri mọ gbe mokaruru ati aparutu gba ni Tinubu fi wọ’le saa keji gẹgẹ bii gomina tẹlẹ ri ni’pinlẹ Eko.
Lati igba ti ọrọ yii ti boode, awuyewuye o ti duro, ti onijagidijagan si ti bẹrẹ si ni f’oju ṣunukun wo gbogbo ọrọ naa. Awọn kan n pe ọrọ to ti kuregbe lati ọdun 2003 ni wọn lọ ji, bẹẹ l’awọn miiran n pe oṣelu buruku ati ẹta’nu naa lo pọju ni’di gbogbo eyi.