Ta Lo Sọ Pe Kosi Ifẹ L’Eko, Ẹ Wa Wo Igbeyawo Peller ati Jarvis Bo Ṣe Dun To

Ta Lo Sọ Pe Kosi Ifẹ L'Eko, Ẹ Wa Wo Igbeyawo Peller ati Jarvis Bo Ṣe Dun To

Bi ariran kankan ba sọ asọtẹlẹ rẹ ṣaaju, eeyan o j’iyan pe irọ ni. Awọn majesin meji to kan ṣ’ere ọwọ l’ori TikTok, kobo-kobo ikeji kati-kati gan-an l’awọn miiran ka a si. Afi bi kinni naa ṣe di ootọ mọ gbogbo aye l’ọwọ.

A ti n ri igbeyawo l’aarin awọn irawọ ori ayelujara, amọ ṣa eyi yatọ. Ọna ti ere ifẹ Peller ati Jarvis yii gba wa o ṣ’ara-ọtọ pupọ.

Ẹsẹ o gb’ero ni’lu Eko, ohun to bẹrẹ bi ibaraẹnisọrọ l’oju opo TikTok lo wa pada d’ohun ti awọn gbajumọ ati ilumọọka nilu Eko ati jina rere gan-an pẹlu wa n pa’wọ pọ lati ṣe ayẹsi rẹ.

 

Ẹ ranti pe ni bi ọdun meji sẹyin ni ibaṣepọ Peller ati Jarvis bẹrẹ gẹgẹ bi ojubanirẹ ara wọn l’ori ayelujara, Kẹrẹ-kẹrẹ wọn f’oju rin’ju. O di pe iṣẹ n da wọn pọ l’oju aye, ti ina ogo awọn mejeeji si bẹrẹ si ni ran ara wọn.

Laipẹ rara ibaṣepọ awọn mejeeji ti n wọ, t’awọn aye si ti n da’na ifẹ si wọn l’aarin. T’oun ti bẹẹ, n ṣe ni okiki awọn mejeeji bẹrẹ si ni buyọ si, afi bi ina ati ẹtu.

Botilẹjẹ pe ọrọ ifẹ awọn mejeeji yii ko ja geere bẹẹ l’atari awọn akọsilẹ aigbọraẹniye, ati ikunsinu lẹkọọkan, koda oni igba ti Peller fẹ wa ara rẹ pa nitori ọrọ ifẹ wọn ti ko wọ.

Amọ ṣa, wọn pada ri ibi ire sọ ẹru ka. Inu oṣu kẹfa ọdun yii ni ile-itura nla kan ni’lu Accra ni orilẹ-ede Ghana ni Peller ti da ẹnu igbeyawo iyẹn ‘proposal’ kọ Jarvis. Ti igbeyawo ibilẹ ni’lu Benin to jẹ ilu iyawo naa si tẹlẹ fun eto mọ-mi-n-mọ-ọ iyẹn ‘introduction’ ati owo-ori iyẹn ‘bride-price’ ni sisan.

Ọjọru (Wednesday) to gbẹyin ninu oṣu keje ni wọn ṣe igbeyawo kootu, ti oni ọjọ Abamẹta Satide ọjọ kinni oṣu kẹjọ si jẹ ọjọ igbeyawo alaṣọ funfun ti wọn pe akori rẹ ni #JP2026, eyi ti ọgọrọ awọn ilumọọka ati ẹni-igba-oju-mọ ti wa ba wọn k’ẹyẹ. Ninu wọn ni Cute Abiọla, Ṣeun Kuti, GehGeh, Sam Larry, Papaya X, Zinolisky, Nons Miraj ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search