Oṣelu B’oju Ọrẹ Gomina Seyi Makinde Ati Oriyomi Jẹ! Ẹ Wa Gbọ Ohun T’Oriyomi Sọ

Gbajugbaja agbohunsafẹfẹ to tun jẹ adije dupo gomina nipinlẹ Ọyọ, Oriyomi Hamzat ti ni oun wa lara awọn to mu gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ-ẹrọ Seyi Makinde wọnu eto oṣelu to pada sọ di gomina.

O fi kun pe, o yẹ ki wọn gboriyin fun oun fun gbogbo aṣeyọri ti gomina Seyi ti ṣe nipinlẹ Ọyọ ni ọdun mẹjọ to ti lo gẹgẹ bi gomina.

Oriyomi sọ eyi nigba to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ Accord sọrọ pẹlu bi aarin oun ati gomina to gunrege tẹlẹ ṣe n daru si latari oṣelu to ti pin wọn ka bi idibo ọdun 2027 ṣe n bọ lọna.

Agbohunsafẹfẹ naa to jẹ ilumọọka pẹlu eto rẹ, Kọkọrọ Alatẹ, lo ni oun ṣatilẹyin fun gomina nitori oun lero pe yoo ṣe daadaa fun ipinlẹ Ọyọ. O ni awọn kan n sọ pe awọn o le ṣatilẹyin f’oun nitori Seyi ti tun Ọyọ ṣe ṣugbọn oun wa lara awọn to fa kalẹ t’oun si fi han f’awọn eeyan gẹgẹ bi gomina.

 

 

 

O tẹsiwaju pe wọn ti kọ lati gboriyin fun oun pẹlu gbogbo nkan ti iṣejọba naa ti ṣe ni daadaa. O ni ti awọn eeyan ba maa sọrọ awọn ohun mere-mere ti gomina ṣe, wọn o kii ranti oun.

Oriyomi tẹnpẹlẹ mọ pe, kii ṣe nitori owo tabi akanṣe iṣẹ ti gomina maa fun oun l’oun ṣe ti lẹyin, oun kan fẹ ki awọn eeyan ri pe ẹni t’oun fa kalẹ ṣe daadaa ni.

Ọrọ ti Oriyomi sọ yii lo wa pẹlu bi oṣelu ti ṣe pin oun ati gomina ti wọn jẹ imulẹ ara wọn ka. Oriyomi n dije gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ọyọ fun ọdun 2027 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord nigba ti gomina ti fa ẹlomii kalẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search