Emi Ni Tinubu I Ba Ran Bo Ba Ṣe Pe O Fẹ Gba Ọṣun Ni Dandan – Wike

Emi Ni Tinubu I Ba Ran Bo Ba Ṣe Pe O Fẹ Gba Ọṣun Ni Dandan - Wike

Minisita f’ọrọ olu-ilu orilẹ-ede Naijiria, ni’lu Abuja, Nyesom Wike to tun jẹ gomina tẹlẹ nipinlẹ Rivers lo ti sọ ni bọnbọ lai ṣẹ’nu ku pe, bo ba ṣe pe Tinubu fẹ gba ipinlẹ Ọṣun pẹlu agbara kaka, ki ẹgbẹ rẹ le wọ’le ibo gomina to wa’ye kọja, ọtọ ni ọna ti o ba gbe gba.

Wike lo sọ eyi l’oni ni’lu Abuja l’asiko to lọ n ṣ’abẹwo s’awọn agbegbe ti ẹkun omi de abi ṣeeṣe ko de ni agbegbe Maitama ni’lu Abuja.

Ni’bẹ ni Wike ti f’ẹnu kun esi idibo ọjọ Abamẹta (Satide) to kọja ni’bi ti Gomina Ademọla Adeleke ti wọ’le saa keji, to si bori ni ijọba ibilẹ mọkandinlogun (19) ninu ọgbọn, ti Asiwaju Munirudeen Bọla Oyebamiji ti inu ẹgbẹ oṣelu APC t’awọn aye n pe ni AMBO si ṣe ipo keji pẹlu ijọba ibilẹ mọkanla (11) ti wọn ti bo’ri.

Wike ni Gomina Adeleke wọ’le ibo naa nitori Tinubu o lo agbara oke ni, bo ba ṣe pe wọn ko agbara wa ni, gbogbo aye ni iba mọ lai nilo iroyin kankan. Amọ ṣa, Tinubu gba ki gbogbo eto lọ ni mẹlọmẹlọ.

O tẹsiwaju pe, bo ba ṣe pe Tinubu fẹ mu ọrọ ibo naa ni dandan ni, oun i ba wa ni’kaleẹ ni’pinlẹ Ọṣun, t’oun yoo si san gbogbo ọna lati jẹ ki wọn jawe olubori, o ni Tinubu i ba gbe iṣẹ naa ran oun, ti yoo si ri b’oun ti fẹ, ti Adeleke o si ni r’ọwọ mu, bẹẹ ni ko ni ri nnkan kan ṣe si.

Wike ẹni to ṣi wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ṣugbọn to n ṣiṣẹ ninu ijọba ẹgbẹ oṣelu APC tun fi kun pe, Adeleke ti wọn n sọ naa fẹkan tẹlẹ i ba wa ninu ẹgbẹ oṣelu APC bo ba ṣe pe akude o wọ ọrọ, to si r’ọna l’asiko igba to fẹ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Ko tan si’bẹ, Wike tun sọ asọtẹlẹ pe ijawe-olubori Aarẹ Bọla Tinubu ninu ibo to n bọ l’ọdun 2027 yoo rọrun lati bori fun-un ju ti ọdun 2023 to kọja. Wike ni oun mọ eyi ni amọdaju nitori gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ni wọn ti di ‘akurẹtẹ, alainile-lori, ati alainiyẹ’ ti eyikeyi wọn o si to gbe’na w’oju Tinubu.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search