Yiyọ Bi Jiga Ni Alaga Ti O Ba Fi’bo Gbe Tinubu Wọ’le – Gomina Ebonyi, Nwifuru Ṣe’kilọ

Yiyọ Bi Jiga Ni Alaga Ti O Ba Fi'bo Gbe Tinubu Wọ'le - Gomina Ebonyi, Nwifuru Ṣe'kilọ

Oṣelu ti n fa’na s’ori bọ bayii ni Naijiria, pẹlu bii eto idibo gbogbogboo ọdun 2027 naa ti n Kan’lẹkun gbọngbọn.

Gomina ipinlẹ Ebonyi, Francis Nwifuru lo ti ṣ’eleri pe eyikeyi ninu awọn alaga ijọba ibilẹ ni’pinlẹ rẹ, iyẹn ipinlẹ Ebonyi to ba kuna lati gbe ẹgbẹ oṣelu APC wọ’le ninu idibo gbogbogboo l’ọdun 2027 l’oun ma yọ danu bi ẹni yọ jiga.

Nwifuru l’ọjọ Iṣẹgun (Tuesday) lo ran ọrọ ikilọ naa kokoko bi ifa aditi si eti awọn alaga at’awọn igbakeji wọn ti wọn ṣẹṣẹ bura wọ’le fun l’awọn ijọba ibilẹ mẹtala to wa ni ipinlẹ naa.

Gomina naa ni “alaga ijọba ibilẹ kankan to ba kuna lati borí ni ijọba ibilẹ l’awọn yoo yọ danu, t’awọn yoo si fi kansilọ kan jirọ rẹ”.

Nwifuru tẹsiwaju bayi pe “mo fẹ ki ọrọ yii pa’riwo ninu awọn iwe iroyin ilẹ yii, nitori awa oloṣelu kii yọ ọrọ sọ.”

O kilọ f’awọn alaga naa pe dandan ni fun wọn lati gbe ẹgbẹ oṣelu APC wọ’le ni agbegbe kowa wọn, bi bẹẹ kọ, yiyọ danu bi jìga. O ni eyi to ba fẹ ninu wọn, ko sun lọ ki wọn fi gba agbegbe rẹ mọ l’ọwọ.

O wa rọ wọn lati ri daju pe wọn o fi oju alatako kankan balẹ ni agbegbe kowa wọn pe gbogbo ohun to ba gba ni ki wọn fun lati ri pe gbogbo ibo ni wọn dari rẹ fun ẹgbẹ APC bo ba di l’ọdun 2027.

Lo ba tun rọ awọn to wa ni ipo igbakeji alaga lati fi ọwọ si’bi ọwọ gbe lati ma f’ori gba’ri pẹlu awọn alaga, o ni bi alaga ba di akurẹtẹ ni iṣẹ to kan wọn, ki wọn ma tẹti si imọran ibi lati yaju s’awọn alaga wọn.

Gẹgẹ bii esi ọrọ Gomina, alaga ijọba ibilẹ Afikpo, Timothy Nwachi du’pẹ l’ọwọ Gomina ati awọn eekan oṣelu ni’kalẹ, to si ṣ’eleri pe lailai awọn ko ni ja ẹgbẹ APC kulẹ l’ori igbagbọ to ni ninu awọn pe ibo bi omi ni ẹgbẹ APC yoo fi wọ’le l’ọdun 2026.

Ọrọ Gomina Nwifuru ti ipinlẹ Ebonyi lo n wa’ye l’akoko kanna ti ile-iṣẹ ọlọpa ni orile-ede Naijiria n ṣe’wadi awọn oloṣelu kọọkan ti wọn pe wọn s’ọrọ alufanṣa to le da ilu ru abi sọ oṣelu d’ogun.

Aarẹ Bọla Tinubu wọ’le saa keji l’ọdun 2027 ni ko gba pe Aaye

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search