Ko dun mọ mi b’awọn obi mi ṣe lokiki, akoba ni! – Ọmọ Shina Peters

Okiki ti ọpọ eeyan n fẹ, ti wọn n sare le, ọmọ SSP ni akoba nla ni!

Njẹ ẹ mọ pe Shina Peters, ilumọ-ọn-ka olorin Juju bi’mọ olokiki bi tiẹ t’oun naa wa l’ẹka amuludun, Clarence Peters l’orukọ n jẹ. Iya to bi i ni Clarion Chukwurah ti oun naa jẹ gbajumọ oṣere?

Clarence Peters
Clarence and his Mum

Abi ẹ o ri ọrọ aye bi? Ohun to kọju s’ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlòmíràn bíi ìlú gangan! Nibi tawon ọdọ kan ti n fori fọrun ṣe kawon lokiki, kawon di ilumo-on-ka, tàwọn mi-in sì n yọ ayọ pe gbajumọ ló bí awọn, ọtọ ni ti ọmọ SSP (Sir Shina Peters) yii. O ni  bawọn obi oun mejeeji yii ti jẹ gbajugbaja gan-an l’ohun ti oun nifẹẹ sí rárá, toun si koriira pupọ. O ni ko dun mọ oun pẹ́ẹ̀ pe oun t’ara awọn obi to gbajumọ jade.

Shinand Clarion, then

Clarence lo sọ eyi ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe l’ẹnu lọọlọọ yii, nibẹ lo ti ni latari bi awọn obi oun ti jẹ olokiki lo mu k’oun o ti kekere pinnu pe gbogbo bira t’ohun yoo da l’agbo amuludun ni yoo jẹ l’ẹyin itage nikan. O ni koda ni ibẹrẹ pẹpẹ oun ko ni igbagbọ kikun to ninu ara oun ati ẹbun oun, amọ Iya oun maa n da oun l’ọkan le pe oun gbagbọ ninu ẹbun toun ni, ti ogo oun yoo si bu jade lasiko to yẹ.

Clarence Peters
Clarence, at work directing music shots

F’ẹni ti ko ba mọ, akọṣẹmọṣẹ oludari fidio orin tàwọn eleebo n pe ni “Music Video Diretor” ni Clarence Peters jẹ, orukọ rẹ si wa ninu awọn to kilẹ daadaa nidii iṣẹ naa. Peters kekere tun ṣalaye siwaju pe, iru abuda oun ni lati jẹ eeyan kan to fa’ra sin’ko, bo tilẹ jẹ pe ẹka amuludun loun ti n ṣiṣẹ, ti awọn iṣe oun si maa n saba fẹẹ fọnrere orukọ oun de gbangba. Koda, o tun ni, ni atijọ, ki ọrẹ alajọṣiṣẹpọ oun kan to yi oun l’ọkan pada, oun kii fẹ da orukọ oun mọ awọn fọnran orin ti oun ba dari nitori ati ma bọ si oju aye yii naa ni.

Clarion, her son, Clarence, and the father, Shina Peters

Ọgba bi Clarence Peters ṣe wí eyi n l’aye ba bere si gba ọrọ naa bii ẹni gba igba ẹmu. Bi awọn kan ti n sọ pe bo ba ti wu’ni laaa ṣe imale ẹni, bẹ l’awọn kan n pe ẹni l’ori o ni fila kuku lọrọ aye.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search