Awọn ọmọ Ikọ ologun ilẹ wa ti wọn n koju awọn agbesunmọmi ni ẹkun iwọ oorun ariwa ti wọn ni inagijẹ Operation Hadin Kai ni wọn ti koju awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi ISWAP kan ti wọn fẹ ṣe ikọlu si agọ ọmọ ologun ilẹ wa ti 120 Task Force Battalion to wa ni agbegbe Gonori ni ipinle Borno.
Ikọlu ọhun to waye loganjọ oru ni ikọ awọn ọmọ ologun ni awọn tete ṣakiyesi rẹ ni kiakia leyi to fun wọn l’anfaani lati koju awọn agbesunmọmi naa ti wọn wọle lati agbegbe Mandunari.
Ninu ọrọ kan ti ẹni to jẹ agbẹnusọ ikọ Hadin Kai Lt.-Col. Sani Uba fi lede ni wọn ti ṣalaye pe awọn ti wọn ṣe ikọlu naa o raye wọle si awọn lara nitori awọn tete doju ija kọ wọn.
Uba ni lẹsẹkẹsẹ ni awọn ọmọ ologun parapọ lati ja takuntakun lati rii pe wọn o ba nkankan jẹ ni agọ naa tabi ji awọn nkan ogun kan kan lọ
Awọn ikọ ologun ni nigba ti o da bi pe ẹkọ o ṣ’oju mimu mọ ni awọn kepe ọmọ ogun ori afẹfẹ ilẹ wa lati kun wọn awọn tilẹ lọwọ. Wọn tẹsiwaju pe lẹyin ikọlu ọhun ni awọn lọ kaakiri agbegbe naa ti awọn si ri apa pe awọn ẹlẹkẹru ṣeṣe yan-na yan-na.
Lẹyin ikọlu naa, lara awọn ohun ti wọn ri ko ni awọn ohun ija oriṣiriṣi. Ni itẹsiwaju, Uba ni awọn ọmọ ikọ ologun ti wọn farapa ni wọn ti n gba itọju to peye bayi bẹẹ ni awọn n gbiyanju lati wa awọn ti wọn salọ l’asiko ikọlu naa ri ki wọn le f’oju kata ofin.