Pẹlu iharagaga lawọn ololufẹ ere bọọlu alafẹsẹgba yika aye fi n reti ki idije fun ife ẹyẹ agbaye ti ọdun 2026 bẹrẹ, ki wọn le tun gbadun ere idaraya to laami-laaka julọ ọhun.
Bi awọn ti yoo rin irinajo lọọ wọran lawọn papa iṣere nla lorileede United State of America, Canada ati Mexico, iyẹn awọn orileede mẹta ti yoo gbalejo awọn agbabọọlu agbaye naa, ṣe n gbaradi, bẹẹ lawọn ti yoo maa wo o lori tẹlifiṣan ati ikanni gbogbo lori intanẹẹti ti n mura lati ri i pe awọn fun oju awọn l’ounjẹ daadaa ti idije ba ti bẹrẹ, o ṣetan, iran kuku ni ounjẹ oju.
Amọ pẹlu bi ipalẹmọ yii ṣe n lọ lọwọ, ajọ to n ṣamojuto ere bọọlu alafẹsẹgba kari aye ti wọn n pe ni FIFA (Federation Internationale de Football Association) ti pinnu, wọn si ti kede pe awọn orileede mẹta kan ko ni i lanfaani lati kopa ninu idije fun ife ẹyẹ agbaye ti ọdun 2026, wọn lawọn ti fofin de wọn, awọn ko si fẹẹ ri ikọ agbabọọlu wọn lori papa, ki wọn yaa fidi mọ abẹle wọn.
Awọn orileede mẹta ti FIFA yọ orukọ wọn danu bii ẹni yọ jiga ọhun ni orileede Russia, orileede Congo, iyẹn nilẹ Africa, ati orileede Pakistan.
Ko tan sibẹ o, FIFA ni ifofinde yii ki i ṣe lori idije fun ife ẹyẹ agbaye ti 2026 nikan, wọn ni gbogbo idije ati ifẹsẹwọnsẹ eyikeyii to ba ti le lorukọ FIFA ninu, tabi to jẹ pe FIFA lo ṣeto rẹ, niṣe ni ki wọn ta idi m’ẹyin, ki wọn maa wo gbogbo ẹ lọọkan, iba a jẹ idije bọọlu tawọn obinrin, tawọn ọjẹwẹwẹ ati tawọn agbaagba.
FIFA ni idi tawọn fi fofin de Orileede Russia lọdun 2022 naa lawọn ṣi fi yọwọ kilanko wọn lawo titi doni, awọn ko si ni i yi ipinnu naa pada titi digba ti Russia ba sinmi ogun ti wọn n ba orileede Ukraine ja. Wọn ni ija ati ifẹmiṣofo to waye naa tako ilana ati ofin alaafia ati ajọṣe kari aye.
Ni ti orileede Congo, ẹṣẹ tiwọn ni pe ajọ to n ṣamojuto ere bọọlu alafẹsẹgba lorileede naa Congolese Football Federation (FECOFOOT) ko tẹle ilana ati ofin FIFA. Ajọ FIFA ti ni awọn ko fẹ ki ọrọ oṣelu maa wọ eto bọọlu, tori oku ko papọ mọ iyawo, awọn ko fẹ kijọba oloṣelu kan maa toju bọ ọrọ iṣakoso ere bọọlu alafẹsẹgba labẹle wọn, eyi si lofin ti Congo ṣẹ si. Nigba ti FIFA reti pe ki wọn ṣatunṣe bo ṣe yẹ, to jẹ niṣe ni wọn n foni-in doni-in fọla da ọla lori ọrọ ọhun ni wọn ba gba wọn sẹgbẹẹ, wọn ni ki Congo maa gba bọọlu wọn labẹle wọn titi ti wọn aa fi ṣe ohun to tọ.
Ọrọ ti orileede Pakistan naa jọra pẹlu ti Congo. Eto idibo awọn ti yoo maa tukọ ere bọọlu alafẹsẹgba lorileede naa eyi to waye laipẹ yii ni FIFA sọ pe ko ba ofin tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ṣatunṣe si mu. Wọn ni ki wọn lọọ tẹle ofin tuntun naa, amọ Pakistan ko ti i ṣetan lati ṣe bẹẹ. Eyi lo mu ki FIFA binu gbọn orukọ wọn yọ.
Pẹlu ipinnu ti FIFA ṣe yii, wọn ni bi eyikeyii lara awọn orileede ti wọn fofin de wọnyi ba fẹẹ tọrọ aforijin, ti wọn si ti ṣatunṣe, afi ki wọn kọwe si awọn, amọ ki i ṣe ni yajoyajo yii o, tori awọn ko tiẹ raaye dida orileede kan lohun ifofinde bayii na, ki wọn sọ gbogbo ẹbẹ ati atotonu wọn di ọjọ mi-in ọjọ ire, ki wọn si gbagbe kikopa ninu idije fun ife agbaye ti 2026, tori reluwee to ti ṣikọ ni, ko ṣee ṣẹwọ si mọ.