Gbajugbaja Oṣere Tọkọtaya nni, Lateef Adedimeji ati Adebimpe Oyebade Adedimeji ni wọn ti dawọ idunnu lori bi wọn ṣe yọ ayọ Ibẹta Ọkunrin lanti lanti ti Ọlọrun ṣẹṣẹ fi jinki wọn.
Adedimeji lo fi Idunnu, Ayọ ati Idupẹ han ninu fọnran kan to fi lede loni lori ikanni ibanidọrẹ Instagram rẹ. Fọnran ọun ṣe afihan awọn mejeeji pẹlu ibọsẹ ọmọ mẹta lati sami awọn Ibẹta naa.
Nigba to n fi idunnu rẹ han, o ni oun dakẹ lẹnu ọjọ mẹta yii nitori oun n yọ ayọ oore Ọlọhun to fun oun latara Iyawo alalubarika ati awọn Ọmọ ti Ọlọhun fi ta oun lọrẹ. Fọnran yii ti wa mu ajọyọ wa laarin awọn Alabaṣiṣẹpọ ati awọn Ololufẹ ti wọn ba idile naa yọ lori awọn Ogo wẹẹrẹ naa.
Ti ẹ o ba gbagbe, Ọjọ Kejidinlogun oṣu Kejila Ọdun 2021, ni awọn mejeeji jọ ṣe igbeyawo alarinrin. Ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn ti fi aitete bimọ sọrọ si wọn lati ọdun ti wọn ti ṣe igbeyawo. Iroyin ayọ yii ti wa mu ọpọlọpọ Ololufẹ awọn oṣere naa sọ pe yeye wọn ti pada di ayẹyẹ.