Portable Ọlalọmi Bi’mọ Tuntun Lẹyin ti Carter Efe Fi Ẹsẹ Lu Portable Ni Alubami

Aṣalẹ anaa lagbara pupọ lagboole amuludun ni ipinlẹ Eko ati ni orilẹ-ede Naijiria lapapọ. Ifigagbaga ẹṣẹ kikan laarin awọn ilumọọka amuludun meji, iyẹn olorin, Portable Ọmọ Ọlalọmi ati alawada, Carter Efe.

Aree ẹṣẹ kikan naa lagbara pupọ to jẹ pe, lati ibẹrẹ ayo naa ni Carter Efe ti bẹrẹ si ni ko ẹsẹ bo “Ọmọ Ọlalọmi” ni gbogbo ara ti de opin ija naa.

Oore-ọfẹ pe Carter Efe ga nilẹ, to si tun ki diẹ ju Portable lọ jẹ ki ọwọ ẹṣẹ rẹ ba Portable daadaa, ti iwọnba ẹṣẹ Portable to kan Carter Efe ko si fi bẹ tu irun kankan lara rẹ.

Ki ija naa to pari ati lẹyin to pari lo ti foju han gedegbe pe ọwọ iya ba Portable gidi gan-an, ti ko si le e pa mọra. Ohun iyalẹnu ninu gbogbo ọrọ yii ni pe, l’asiko ti Portable n ja ija yii lọwọ ni aya rẹ akọfẹ to n jẹ Bẹwaji naa n rọbi to si bimọ tuntun. Lariwo miran ba tun sọ gee.

Igba akọkọ kọ ni eyi ti Portable yoo kopa ninu ifigagbaga ẹṣẹ kikan pẹlu awọn ilumọọka miran, Charles Okocha ati Kevin Power ti pa Portable pada to si fi ẹyin awọn mejeeji bẹ ilẹ ṣugbọn okiki ija eleyii kan pupọ yatọ nitori ọpọ awọn ile-iṣẹ nla ati ẹni nla lo ṣe agbatẹru rẹ, ti ọpọ awọn ilumọọka bi Peller, Tunde Perry, Timaya, D’banj, Ayox Cute Abiola, Seun Pizzle, Jidex, ati bẹẹ bẹẹ lọ naa wa wo iran wọn.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search