Wahala! Seyi Vibez S’ọrọ Buruku Si Adekunle Gold ati Aya Rẹ, Simi Ni Ija Nla Ba Bẹ Silẹ

Seyi Vibez ati Adekunle Gold

Awọn ọrọ buruku pau bi ibọn lo n bọọlẹ lati ẹnu gbajugbaja olorin takasufe t’awọn ọdọ nigboro n kojẹ gidigan lọwọ yii iyẹn Seyi Vibez si akẹgbẹ rẹ miiran to n naa jẹ irawọ olorin takasufe ti wọn pe ni Adekunle Gold abi AG Baby, to fi mọ aya rẹ Simi ti oun naa jẹ irawọ olorin to yaayi.

Ni nnkan anaa ode yii ni awọn ọrọ kobakungbe bẹrẹ si ni jade lati ẹnu Seyi Vibez, to si pe Adekunle Gold ati Simi ni awọn orukọ to buru jayi.

Gbolohun kan ti Adekunle Gold pe ninu orin rẹ tuntun kan to ṣẹ gbe jade to pe akọle rẹ ni “Life of the Faaji” lo jọ pe o fi ta si Seyi Vibez, ti eyi si gbodi l’ara Seyi, to fi bẹrẹ si ni sọ ọrọ burku.

Abala orin naa lọ ba yii pe “They love my Fuji, this no be Fuji moto” iyẹn ni pe o ṣeeṣe ki Adekunle Gold o ma gbe awo-orin to ṣe to pe ni “Fuji” ga bori awo-orin miiran ti Seyi Vibez ṣe to pe ni “Fuji Moto.”

Abala orin to bi wahala

Aṣamọ ọrọ yii ninu orin Adekunle lo fa awọn esi buruku ti Seyi Vibez sọ wọnyi:

“Ngbọ baba Duduke, ṣe lootọ ni pe iya Duduke fẹran lati maa ba ọmọ kekere lo pọ? Ko ni yẹ ẹ.

“Bi wọn ba bi baba Adekunle Panda (Gold) da, ko jade wa ba mi fa, mobura!

“Adekunle Panda (Gold), agba yẹyẹ ni ọ, o ko mọ faari rara.”

Botilẹjẹ pe ọpọ awọn ololufẹ awọn olorin mẹtẹta lo ti n gbaruku ti wọn, ti wọn si n daabobo ololufẹ wọn ṣugbọn Adekunle Gold funra rẹ na ti fọ esi buruku pada to si n pe oun kii ṣe ẹgbẹ Seyi nitori oun ti n gbe awọn orin manigbagbe jade ki Seyi to ronu Fuji Moto laye.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search