Sandra Edoho to jẹ iyawo tẹlẹ fun Frank Edoho, gbajugbaja sọrọsọrọ ti fi ẹsun kan-an pe niṣe lo maa lu oun nigba t’awọn wa papọ. O sọ eyi lẹyin ti iroyin jade pe oun ati gbajugbaja olorin, Chike jọ n ṣe wọlewọde lasiko to ṣi wa nile Frank.
Sandra l’awọn eeyan ti bẹnu atẹ lu pe o n ṣe ṣina lẹyin ti iroyin pẹlu awọn ẹri fi han pe oun ati Chike jọ n ni nkan pọ.
Nigba to fesi si awọn ọrọ naa, Sandra ti ko tako ẹsun ti wọn fi kan lo fẹsun kan Frank pada pe kii ṣe ẹtọ gẹgẹ bii baba ati ọkọ bẹẹ lo tun maa n k’obinrin titi kan awọn tiwọn lorukọ lawujọ nigba t’awọn wa pọ gẹgẹ bi lọkọlaya.
Gbogbo alaye yii lo ṣe ninu fọnran kan to fi lede nibi to ti n sọ pe oun kọ lati jẹ iyawo o ni nọbi ti ọpọ eeyan n pe oun nitori oun ni awọn ẹri lọwọ to n ṣafihan gbogbo iṣẹ ọwọ Frank naa.
O wa fi fọnran kan sita lati gba ẹsun to fi kan Frank lẹyin bẹẹ lo rọ lati jade wa pẹlu otitọ nitori o gbọdọ gba ẹbi tiẹ ninu ọrọ yii.
Ọrọ Frank ati Sandra lo ti n ja rọnyin rọnyin lori ẹrọ ayelujara lati bii ọsẹ diẹ lori ẹsun aiṣootọ ninu igbeyawo.