Ọọni Ṣe Ikilọ Nla F’awọn Ọba Alade L’ori Eto Aabo Ilẹ Yoruba

Ọọni ti Ile-ifẹ, kabiesi Enitan Babatunde Ogunwusi, Ọjaja Keji lo ti rọ awọn l’ade-l’ade ni ilẹ Yoruba lati lo ilana iṣenbaye ati ọgbọn awọn alalẹ lati fi ṣẹgun igbesunmọmi, ijinigbe ati awọn iwa ọdaran miiran l’ẹkun yii.

Gẹgẹ bii atẹjade ti agbẹnusọ Ọọni, Moses Ọlafare fi si’ta, kabiesi naa s’ọrọ l’asiko ajọdun Ifa ti ọdun 2026, ni’bi to ti n pe fun iṣọkan ati ifọwọsowọpọ l’aarin awọn ọba alade gbogbo, ki wọn o le wa’wọ iwa ọdaran ati awọn ọdaran bọ’lẹ l’agbagbe kowa wọn ati l’ẹkun ilẹ Yoruba l’apapọ.

Ọọni pe “A gbọdọ ṣe akojọ awọn agbara ibilẹ wa ati orirun wa lati le le awọn ajinigbe, awọn jankoriko (banditi) ati awọn oniwa ọdaran miiran kuro ni agbegbe wa ati ni orilẹ-ede Naijiria l’apapọ. Ohun ti awọn baba-nla wa duro fun ni idajọ ododo, alafia ati ijumọgbepọ ninu irẹpọ. Gẹlẹ bẹẹ ni awọn naa gbọdọ ṣe.

“A gbọdọ jumọ koju iṣoro awọn jankoriko ati ajinigbe. O to gẹ! Awọn eniyan wa yẹ ki wọn le rin, ki wọn le gbe igbe-aye ailewu. Awọn ori-ade gbogbo gbọdọ ko ọrọ aabo ilu wọn le ọkan, ki wọn o si ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo gbogbo.”

Ọjaja Keji o ṣai m’ẹnuba ba pe iṣoro eto aabo jẹ pataki fun ijọba apapọ lati mojuto ṣugbọn to tun lu Aarẹ Bọla Tinubu l’ọgọ ẹnu fun igbiyanju to ti ṣe.

Lakotan, Ọọni lo anfaani ajọdun Ifa lati fi wure fun idande l’ayọ awọn akẹẹkọ ati olukọ ti wọn jigbe ni ipinlẹ Ọyọ ati ipinlẹ Borno.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search