Adẹrinpoṣonu Bovi Ugboma ti ọpọ eeyan mọ si Bovi ti ni oun maa ṣatilẹyin fun igbeyawo to ba tuka koda oun maa n ṣajọyọ nigba t’awọn l’ọkọ l’aya ba lọ l’ọtọọtọ nitori pe ọpọ igba o maa n mu ifọkanbalẹ wa fun awọn ti wọn ba ha sinu igbeyawo.
Nigba to n sọrọ lori eto kan ti wọn pe si, Bovi ni ipinya daa ju ki eeyan wa ninu igbeyawo to ni ọpọlọpọ hila-hilo ti ọkan awọn mejeeji o ni alaafia.
O ni oun maa n ṣajọyọ ti igbeyawo ba tuka nitori oun mọ pe ọkan lara awọn l’ọkọ l’aya naa tabi awọn mejeeji ni ko si alaafia fun ninu igbeyawo naa.
O fikun pe ero oun lori igbeyawo ko tumọ si pe igbeyawo rọrun nitori oun gan ti ri awọn adojukọ to pọ ninu igbeyawo ọlọdun mẹtadinlogun t’oun.
Bovi ni kii ṣe pe igbeyawo oun rọrun nitori oun fẹ iyawo ni ọmọ-ọdun mọkandinlọgbọn ti oun si ti n pese fun ẹbi lati ọdun mẹtadinlogun sẹyin.
O tẹsiwaju pe lati sọrọ lori bi igbagbọ aye atijọ ṣe ni pe ki ọkunrin nikan maa pese ṣugbọn o ṣe pataki ki obinrin naa ni iṣẹ gidi lọwọ lati l’owo lọwọ.