Awọn Boko Haram Pa Awọn Sọja Naijiria, L’Amẹrika Ba Ni K’awọn Ọmọ Wọn O Ma De Naijiria

Ikọlu kan lo waye laṣalẹ Ọjọru Wednesday si ibudo ọmọ ologun (military base) orilẹ-ede Naijiria kan to wa ni Benisheikh nijọba ibilẹ Kaga, nipinlẹ Borno. Ado iku, ibọn ati awọn ohun ija miran ni wọn fi ṣe ikọlu si ibudo ologun naa ati awọn ile itaja to wa ni arọwọto.

Alaye to n jade ni pe, igun ISWAP ninu ikọ ẹlẹkẹru agbesunmọmi Boko Haram lo wa nidi ikọlu naa to waye fun bi wakati melo kan, leyi to ba awọn ologun lẹja fuu.

Ẹwẹ, botilẹjẹ pe onka iye awọn ọmọ ologun ni ibudo naa to faragba ni pato ni ko ti hande ṣugbọn alag ijọba ibilẹ naa, Zanna Ajimi fi idi rẹ mulẹ pe ọgagun kan ti orukọ rẹ n jẹ O.O Braimoh naa sun loju ija latari ọkọ ologun to taku lasiko to fẹ ja ajabọ kuro ninu ikọlu naa.

Ikọlu yii lo si tuntun julọ ninu iru rẹ to ti n waye latọwọ ikọ agbesunmọmi sawọn eleto aabo lẹkun ila-oorun ariwa orilẹ-ede Naijiria.

Ẹwẹ, orilẹ-ede Amẹrika lo ti kesi awọn aṣoju rẹ ni orilẹ-ede Naijiria to wa ni ilu Abuja lati pada silẹ, pẹlu ikilọ fun awọn ọmọ Amẹrika lati ma de nnkan ipinlẹ mẹtalelogun (23) ni Naijiria nitori iṣoro eto aabo bi ijinigbe, igbesunmọmi ati iwa ọdaran miran.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search