Agbo tiata ati ẹka amuludun lapapọ dawọọ idunnu bi ogbontarigi oṣerebinrin nni, Ṣọla Ṣobowale ṣe fi ọmọ rẹ, Olamide f’ọkọ niluu Ibadan.
Ayẹyẹ ọhun lo ṣoju awọn ọtọkulu loriṣiriṣi lati ori awọn oni tiata, to fi mọ awọn eeyan nla-nla lawujọ.
Ayẹyẹ naa bẹrẹ pẹlu aṣalẹ “Iya ati Ọmọ,” ki wọn to bọ si ifọmọfọkọ nilana aṣa ilẹ Yoruba. Lẹyin naa ni wọn ṣe wẹjẹwẹmu nibi ti gbajugbaja olorin ẹmi nni, Yinka Ayefele ati ojinmi onkọrin Fuji, Adewale Ayuba ti fi orin ati ilu da awọn alayọ jaa l’ara ya.
Gomina Seyi Makinde & Toko Taya
L’ara awọn ti wọn wa yẹ awọn tọkọtaya tuntun naa si nibi ayẹyẹ ọhun ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ-ẹrọ Seyi Makinde, yatọ fun awọn oṣere bii Shaffy Bello, Aisha Lawal, Toyọsi Adesanya, Fẹmi Adebayọ, Nancy Isime, Tokẹ Makinwa, Biọla Adebayọ, Bisọla Aiyeọla ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn jade wa ba Ṣọla Sobowale yọ ayọ ifọmọfọkọ naa.