Ikọ awọn ọmọ ologun ori ilẹ 12 Brigade Nigerian Army ti doola awọn eeyan mẹtalelogun lẹyin ikọlu awọn afurasi agbesunmọmi loju ọna Ayegunle–Bunu ni agbegbe ijọba ibilẹ Kabba-Bunu ni ipinlẹ Kogi.
Eleyi lo jẹyọ ninu akọsilẹ iṣẹ ti wọn fi lede f’awọn oniroyin. Gẹgẹ bii akọsilẹ naa ṣe fi han, iṣẹlẹ naa waye ni kutukutu aarọ yii nigba ti awọn afurasi agbesunmọmi naa di titi ti wọn si ko awọn arinrin-ajo ti ko niye.
Ikọ awọn ọmọ ologun naa ti wọn wa labẹ agbegbe Kabba ni wọn dahun ni kia si ipe pajawiri ṣugbọn awọn afurasi naa sa lọ ki awọn ikọ naa to de bẹ.
Wọn ni nigba t’awọn de ibi ti iṣẹlẹ naa ṣẹ, wọn ri eeyan meji ti wọn ti jẹ Ọlọhun nipe, awọn marun mii ti wọn farapa, ọkọ akero meji ati ọkọ ajagbe kan ti wọn fi silẹ l’ẹgbẹ titi.
Gẹgẹ bi akọsilẹ naa, lẹsẹkẹsẹ l’awọn ikọ naa bẹrẹ igbiyanju lati le awọn ọdaran naa mu leyi to mu ki wọn ri awọn mẹtalelogun doola nigba ti awọn ọdaran naa fi wọn silẹ salọ latari ifungunmọ ti ikọ naa fun wọn.
Wọn tẹsiwaju pe awọn ti wọn farapa ti wa nile iwosan bayii fun itọju to peye nigba ti iṣẹ n lọ lọwọ lati mu awọn ọdaran naa ki wọn le doola awọn to ku.
Iṣẹlẹ yii tubọ n tọka si bi eto aabo orilẹede Naijiria ṣe n f’ojoojumọ mu ibẹru ba awọn araalu.