Ko Si Ireti Fun Awọn To L'ẹbun Nipa Imọ Sayẹnsi Lorilẹ-ede Yii - Seun Kuti
Gbajugbaja olorin, Seun Kuti ti bu ẹnu atẹ lu aisi ipese to peye lati ṣatilẹyin fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti wọn ni ẹbun, to si n jiyan pe ọpọ awọn ti wọn l’ẹbun lo jẹ pe anfaani perete lo wa fun wọn lati mu agbega ba ẹbun wọn.
Nigba to n sọrọ lori bi nkan ṣe ri lorilẹ-ede yii, o ni eeyan le ni imọ gidi ni awọn ẹka bii imọ-ẹkọ, imọ-ẹrọ ati bẹẹ bẹẹ lọ to si jẹ pe wọn o ri nkan gidi ati atilẹyin to peye lati ṣe iranwọ fun wọn, ki wọn le tẹsiwaju.
Gẹgẹ bo ṣe wi, iyi wa fun awọn iṣẹ to niṣe pẹlu iṣẹ-ọwọ ati amuludun ju awọn to ni ṣe pẹlu imọ-ọtun, iwadi ati imugbooro ọpọlọ lọ.
Seun beere pe ki wọn tọka si ibi ti awọn ti wọn ni lọkan lati di onimọ sayẹnsi, onimọ ẹrọ ati onimọ nipa iwe le yi si fun atilẹyin, bẹẹ lo ni ọpọ awọn ọdọ ti wọn ni ẹbun ni ko si alakalẹ fun wọn lati yege.
O fikun pe awujọ n fi ọkan si bibeere lọwọ awọn eeyan nipa awọn iṣẹ ọwọ ti wọn ni, ti wọn si n f’oju pa awọn ti wọn ni ẹbun l’awọn ẹka to ṣe pataki rẹ.
Seun ni titi di igba ti ijọba ba pese awọn akanṣe eto fun gbogbo awọn to l’ẹbun, o maa nira fun ọpọ awọn ọdọ lati ri anfaani ti yoo ran agbara wọn lọwọ.