Iru Ifẹ Davido ati Chioma Yii S'ọwọn, Ẹ Wa Gbọ Ohun Ti Wọn Fipamọ Si'ra Wọn L'ọwọ
Gbajugbaja olorin, David Adeleke, ti gbogbo eeyan mọ si Davido lo ti ni iyawo oun, Chioma Adeleke ni alakoso aye oun.
Davido ni fọnran kan gbe jade ni’bi to ti n pe iyawo rẹ lati fi ẹgbẹrun mẹrin owo dọla ranṣẹ si amugbalẹgbẹ rẹ, Lati nitori oun o ri owo gba bayi.
Ninu fọnran naa lo ti ni iyawo oun lo maa n ṣamojuto owo nitori inakuna oun pọ bẹẹ lo ni oun ni alakoso aye oun.
Davido ati Chioma ni wọn ṣe igbeyawo alarinrin ni ọdun 2025 lẹyin ti ibasepọ wọn de gbangba ni ọdun 2018.
Ọpọ awọn ololufẹ wọn ni wọn ti ki Chioma fun suuru rẹ pẹlu awọn ariwisi oriṣiriṣi ti Davido maa fa lori ayelujara latari ibaṣepọ rẹ pẹlu awọn obinrin mii.