Toyin Abraham Kọ Lo Da Igbeyawo Mi Ru, Ẹ Sinmi Irọ - Iyan Aladuke
Iyawo oṣerekunrin Femi Adebayo ti wọn ti tuka bayi, Omotayo Sanusi ti ọpọ eeyan mọ si Iyan Aladuke, lo ti jade wa ko ọrọ kan to n lọ pe oṣerebinrin Toyin Abraham ni nkan ṣe pẹlu igbeyawo rẹ to daru nu.
Nigba to n ṣalaye pẹlu atẹjade gigun kan lori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ, o ṣapejuwe ọrọ naa gẹgẹ bi irọ, to si n ni oṣerebinrin naa o mọ nkankan nipa awọn ipenija to tu igbeyawo oun ka.
O ni niṣe l’oun mọọmọ ma sọrọ lori gbogbo awọn iroyin ofege to n tan ka nipa igbeyawo oun ati Femi sugbọn oun nilo lati jade sọrọ bayii nitori ọpọ awọn eeyan ti n mu lootọ.
Omotayo ni iroyin pe Toyin lo ṣ’eke f’oun pe ọkọ oun n yan ale ni’bi ti wọn ti n ya iṣẹ fiimu kan leyi to fa t’oun fi lọ ba wọn ja, kii ṣe ootọ rara. O ni koda, oun o ba ẹnikẹni ja nibi ti wọn ti n ṣe fiimu nitori ọkọ oun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ibi fiimu ti wọn n sọ yii, oun l’oun n gbọ ounjẹ fun gbogbo awọn ti wọn ṣiṣẹ nibẹ gẹgẹ bi atilẹyin fun ọkọ oun tẹlẹ. O fi kun pe ki ẹnikẹni t’oun ba ti d’oju ija kọ jade wa sọ to ba jẹ bẹ.
O ni, oun dakẹ lati ọjọ yii nitori ọwọ t’oun ni fun gbogbo awọn t’ọrọ kan ati pe oun fẹran alaafia ju ija igboro lọ, ṣugbọn ki ẹnikẹni ma fi didakẹ oun pe gbigba irọ lootọ.
Ninu ọrọ mii to fi sori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ kan-naa lo ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn eeyan ṣe sare gbe iroyin ofege ti wọn fi lede nitori oun, ṣugbọn wọn n bu ẹnu atẹ lu bi oun ṣe jade wa sọrọ lori rẹ.
Alaye yii ni Omotayo ṣe lẹyin ti agberoyin jade lori ayelujara kan fi ẹsun kan Toyin pe oun lo sọ fun Omotayo pe ọkọ rẹ ati Funke Akindele jọ ni nkan pọ, eyi to fa ti iyẹn fi wa ba Funke ja nibi sinima naa.
Gẹgẹ bi onitọun ṣe sọ, o ni eyi lo fa ti igbeyawo wọn fi tuka. O fi kun pe lẹyin naa ni Funke kọ ẹyin awọn agbesinima jade si Toyin, leyi to ṣokunfa bi ko ṣe dahun kiki Toyin nibi igbejade sinima Iyabo Ojo ninu oṣu kẹrin.
Femi Adebayo ati Omotayo Sanusi ni wọn ṣe igbeyawo ni ọdun 2016 ti ọlọrun si fi ọmọ kan jinki wọn. Iroyin ituka igbeyawo wọn kọkọ gb’ode kan nigbati agberoyin jade lori ayelujara kan ni Femi ti ko ẹru kuro ni’le nitori ifooro ẹmi lat’ọwọ iyawo rẹ.
Lẹyin eyi ni Omotayo fi gbe sita pe wọn ti le oun n’ile tọmọ tọmọ ati nibi t’oun ti n ṣ’owo. Eyi lo mu ki mọlẹbi Femi kan jade lati wa ko ọrọ naa danu pe bẹẹ kọ l’ọrọ ri. O ṣalaye pe Femi gba ile fun nitori awọn banki ti gbẹsẹ le ile naa latari owo to gba lati ya fiimu kan, eyi ti ko ri san.
Oṣerebinrin kan to jẹ ọrẹ Omotayo timọ-timọ naa jade wa sọrọ pẹlu awọn akasilẹ ohun nipa iṣẹlẹ naa.
Igba akọkọ re ti yoo sọrọ lori ọkan ninu awọn ọrọ to n lọ nipa igbeyawo rẹ to tuka ṣugbọn Femi o tii jade sọ ohunkohun lati igba ti ọrọ naa ti bẹrẹ.