Ẹ Mójútó Igbèsè Nàìjíríà Tori Ìṣòro Ìnáwó L’ọ́jọ́ Iwájú – Awọn Amoye Eto Ọrọ Aje

Ìkìlọ̀ tuntun ti jáde lórí gbèsè orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń gòkè sí i, àti bí ó ṣe lè ní ipa lórí ìṣúná àti ìdàgbàsókè. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe fi hàn, Àwọn amòye lóri ètò ọrọ-aje sọ pé bí gbèsè ṣe ń pọ̀ sí i yìí ń fa ìbànújẹ, nítorí pé púpọ̀ owó ìjọba ń lọ sínu sísan àwọn gbèsè tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀, dípò kí a lo fún iṣẹ́ ìdàgbàsókè bí ètò ẹ̀kọ́, ìlera tó yẹ kooro àti àwọn oun amáyédẹrùn.

Wọ́n ṣàlàyé pé gbèsè orílẹ̀-èdè ti ń gòkè lọ́dún sí ọdún, nítorí ìjọba ń gbà owó láti bo àìlera ìṣúná àti láti ṣe iṣẹ́ amáyédẹrùn àti àwọn iṣẹ́ pàtàkì míì.

Síbẹ̀, àwọn amòye ń bẹ̀rù pé bí ìjọba bá ń tẹ̀síwájú lórí gbèsè gbígbà naa láì fa owó wọlé, ó lè dá ìṣúná orílẹ̀-èdè rú ní ọjọ́ iwájú.

Wọ́n wá rọ ìjọba pé kí wọn gbé ìgbésẹ̀ kánkán láti mú kí owó tí orílẹ̀-èdè ń pa wọlé pọ̀ sí, kí wọ́n tún eto ìkójọ owó orí dáa, kí wọ́n yí ètò ọrọ-aje padà, kí wọ́n sì dín ìgbẹ́kẹ̀lé lórí gbèsè kù.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ ìjọba sọ pé àwọn gbèsè naa ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè àti ṣíṣe àwọn oun amáyédẹrùn, àwọn olùṣàkóso ọrọ-aje ń bẹ̀bẹ̀ fún ìmúlò tó dá lórí ìṣọ́ra àti ìmúlò ọgbọ́n kí ó lè dájú pé yóò yọrí sí ìdàgbàsókè gidi. Ìpè yìí wáyé ní àkókò tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tó ń gòkè ń dojú kọ ìṣòro gbèsè káàkiri àgbáyé.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search