Ilumọọka aṣoju awọn ile-iṣẹ to tun jẹ ọmọ fun gbajugbaja oṣere binrin nni Iyabo Ojo, Priscilla Ojo ti fi ero ọkan rẹ han lori igbẹkẹle ati ifọkantan paapaa julọ awọn ohun to rọ mọ fifẹ ẹni to jẹ gbajugbaja to si n tọka si pe oun jẹri ọkọ oun, Juma Jux to jẹ gbajugbaja olorin ni Orilẹ-ede Tanzania pẹlu gbogbo ifungunmọ to wa pẹlu fifẹ ẹni to jẹ ilumọọka.
Nigba to n sọrọ lori ifọrọwanilẹnuwo kan lo ti ṣaṣọ loju bi igbeyawo ṣe ri ati bi oun ṣe n gbe igbe-aye pẹlu bii ọpọlọpọ oju ṣe wa lara awọn.
Nigba ti o n sọrọ nipa aiṣootọ ninu igbeyawo eyi to wọpọ laarin awọn amuludun, o ni ifọkantan ati ikoraẹninijanu lo jaju ninu igbeyawo oun.
O ni ọkọ oun ba fẹ ṣe bẹẹ, ọwọ ẹ lo wa ṣugbọn oun jẹri ẹ nitori o ni ikoraẹninijanu. Priscilla tẹsiwaju pe lootọ fifẹ ẹni to jẹ gbajugbaja olorin maa n mu ọpọlọpọ ololufẹ wa ṣugbọn iwa ọmọluabi ti eeyan ba ni lo maa n ṣiwaju. O ni lootọ awọn obinrin imi maa n ṣe aṣeju ṣugbọn ti ọkọ atiyawo ba ti di opo adura mu ti ọkọ si mọ oun to fẹ ko ni si wahala kankan.
Ti ẹ o ba gbagbe ni ọdun to kọja ni Priscilla ati Juma Jux ṣe igbeyawo alarinrin leyi to waye ni Orilẹede Naijiria ati Tanzania.