Gudugbẹ! Ẹyi Ni Aṣiri Ija Toyin Abraham ati Abike Shuga

Awuyewuye ti n lo lori ẹrọ ayelujara bayi latari ariyanjiyan kan to bẹ silẹ laarin gbajugbaja oṣere tiata nni, Toyin Abraham, ati ẹni ti wọn ti jọ ṣiṣẹ pọ ri ti o so ti fi igba kan jẹ ọmọ afẹ rẹ, Pelumi Olawuni ti gbogbo eeyan mọ si Abike Shugaa.

Awuyewuye ti n lo lori ẹrọ ayelujara bayi latari ariyanjiyan kan to …

Awuyewuye ti n lo lori ẹrọ ayelujara bayi latari ariyanjiyan kan to …

Awọn afurasi agbebọn ni wọn ti ji awọn arinrin-ajo kan, pẹlu awọn …

Ajọ to n ṣakoso ere idaraya l’agbaye (World Athletics), ti kọ ibeere …

Awuyewuye yii bẹrẹ lẹyin ti Abike fi fọnran kan lede lati ṣalaye bi ọrọ ṣe jẹ lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti awọn eeyan ti fi oju rẹ gbolẹ lori ẹrọ ayelujara nitori ko ba Toyin Abraham ṣe mọ. O ni oun ti pa ọpọlọpọ iwọsi mọra latari pe oun o fẹ sọrọ, koda ọrọ naa ta ba awọn obi, ẹgbọn, aburo ati awọn ọrẹ oun nitori gbogbo igba ni awọn eeyan maa n sọrọ ta ba oun lori ẹrọ ayelujara eyi to mu ki oun ṣe fọnran naa jade.

Nigba to tẹnu bọrọ, o ni pe asiko ti oun n ba Toyin ṣiṣẹ pọ ko gbe oun rara bẹẹ ni ko tun san owo to to fun oun nigba naa. O tẹsiwaju pe ibaṣepọ ti oun ni pẹlu awọn oṣere tiata imi bii Funkẹ Akindele lo fa ti ọrọ awọn ko fi wọ mọ nitori Toyin ri gẹgẹ bii aiṣootọ si oun ni.

Nigba to n fesi, Toyin Abraham ni oun ko ni sọrọ pupọ nitori bi ọmọ lo jẹ si oun ṣugbọn irọ to jina si ootọ lo sọ nipa owo iṣẹ ti oun san fun. O ni oun ri pe o gba gbogbo owo iṣẹ to ṣe pata. Ni ipari ọrọ re, o ni oun ti pinnu lati ma so oun k’oun mọ nitori bi ọmọ ni oun ṣi ṣe mu Abike ati pe oun maa n gbiyanju lati fun awọn ti wọn ṣẹṣẹ n bọ laye ki awọn naa le g’oke.

Ọrọ yii ti wa fa ariwisi oriṣiriṣi, paapaa julọ lori ọrọ Ọga si ọmọ iṣẹ ninu Agodo tiata latari pe eleyii kii ṣe akọkọ bẹẹ ni Toyin kii ṣe ẹni akọkọ ti iru ẹsun bẹẹ maa kan l’agbo awọn oṣere.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search