Gbajúgbajà òṣèré tíátà ní Azubuike Michael ti gbogbo èèyàn mọ sí Zubby Michael, ló ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress, ADC.
Ó sọ èyí di mímọ̀ lórí ojú opo ayélujára rẹ̀, níbi tó ti fi àwọn àwòrán hàn ní ọ́fíìsì ẹgbẹ́ ADC tó wà ní ìlú rẹ, ni Ozubulu, ipinlẹ Anambra pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ni òun ti forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ADC nitori pe àkókò tí tó láti gbé ìgbésẹ̀ yatọ sí atotonu ọrọ ẹrọ ayelujara, ó ṣàlàyé síwájú sí pé ìgbésẹ̀ yìí jẹ́ láti kópa nínú ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ìṣàkóso rere fún gbogbo mutumuwa.
Bíótilẹ jẹ́ pé kò tíì sọ bóyá òun fẹ́ díje du ipò kankan, ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi hàn pé ó ní ìfẹ́ sí òṣèlú ṣáájú àwọn ìdìbò tó ń bọ. Ìgbésẹ̀ yìí ló ti mú ìfèsì oríṣìíríṣìí wá láàárín àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí àwọn diẹ̀ ń fi ọwọ́ sí i, nígbàtí àwọn míì sì ń béèrè bóyá ó ní ìrírí tó pé nínú òṣèlú.